Odò òsùmàrè onídán
Mimi Werna
Edwin Irabor

Ọmọ ìyá mẹ́ta, Udoo, Erdoo àti Eryum tẹ́tí sí orin òjò. Wọ́n fẹ́ jó nínu rẹ̀. Wọ́n fẹ́ fi ọwọ́ kan òsùmàrè tí ó dé sí lójù ọ̀run. Ìyá sọ wipe, "Rárá."

Wọ́n sun ẹkún, látì yí ọkàn rẹ̀ padà. Kò siṣẹ́. Eryum ti lẹ̀ gbìyànjú láti yọ́ jáde kúrò ní ilé lọ bẹ òsùmàrè wò.

1

Ìyá gba mú kí ó tó lè lọ. Wọ́n sọ̀rọ̀ sókè kí Eryum àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin náà le gbọ́.

"Otútù lèé mú ọ," Ìyá ṣọfun. "Òó sí tún fẹ́ràn pẹpẹsúùpù, iwò yoó ní láti jẹ díẹ̀, tí otútù bá mú o," Ìyá sọfun pẹ̀lú ẹ̀rín.

2

Pẹ̀lú ìrètí kí wọ́n bèrè fún ìtàn, ìyá wípé, "Òsùmàrè jẹ́ odò onídán tó ní agbára ìwòsàn. Sùgbọ́n ó wà ní òke sánmọ̀ tí ọwọ́ kò le tó. Tí ó bá ní otútù, òsùmàrè kò le ràn ọ́ lọ́wọ́."

Àwọn ọmọ ronú sí èyí.

3

"Ìyá, ẹjọ̀wọ́̀ ẹ pa ìtàn òsùmàrè wa," Erdoo wí. "Bẹ́ẹ̀ni, ẹjọọ́̀ ìyá, èmi náà fẹ́ gbọ́," Udoo náà fi kun. "Mo sìkẹta," Eryum bẹ̀bẹ̀, pẹ̀lú ìka kékeré mẹ́ta lókè.

"Ẹ jẹ́ ki ǹ wó ná, mmmm," ìyá sọ ọ́ pẹ̀lú àwàdà. "Ó da ẹ̀yin àyànfẹ́, ẹ yí mi ká. Íyá, onítàn ti dé!"

4

Erdoo sáré lọ mú ọmọrogún, igi ìrúsóké tí wọ́n fi ń se ọ̀pá àmì. Ó fi lé ìyá lọ́wọ́. Eryum lọ mú gèlè wá fún ìyá láti wé. Kò kùnà láti fi ìyá sí ipò ọlùpìtàn.


Gbogbo wọ́n jókò láti fi etí sí ìtàn tí wọ́n ti gbọ́ ní ọ̀pọ̀ ìgbà. Udoo fọn fèrè náà, láti ṣọ fún ìyá kó bẹ̀rẹ̀. Ìtàn náà sí bẹ̀rẹ̀.

5

"Nígbà kan, òsùmàrè jẹ́ odó onídán. Ó wà ní ìpamọ́ nínu igbó Mbadede. Nítorí agbára ìwòsàn tí ó ní, ó wà ní sísọ́.

Tí ara rẹ kò bá le, ìwo yóó mu omi náà. Òsùmàrè fẹ́ran láti má pín. Sùgbọ́n kò fẹ́ràn ènìyàn oníwà búburú."

6

"Nítorí idán odò náa, ohun àdídùn ìrẹ̀ ǹgbẹ (aísìkirimù) wà ní ẹ̀ba odò náà! Gbogbo ẹni tí ó bá wá mu omi ma ń gbádùn aísìkirimù yìí, pàápàá àwọn ọmọdé.

Áisìkirimù láti odò yíì jẹ́ àwọn àwò tó jẹ́ pupa, ọsàn, ìyeyé, ewé, sánmọ̀, àlùkò àti èlú."

7

"Ní ọjọ́ kan, ìyá arúgbó oníjọ̀ngbọ̀n kan tí ó n jẹ́ Mbom wá láti ìlú jíjìn. Bí ó ti dé, ó bá ẹ̀sọ́ kan. Ẹ̀sọ́ yíì kò mọ̀ọ́, ara ṣí fuú. Sùgbọ́n kò bìkítà sí ìfura yíì.

Ó tọ́ka ọ̀nà inú igbó yíì, ó sì sọ fún kó bọ̀wọ̀ fún odò náà. Mbọ́m gbà, ó sì lọ sí ibí omi náà."

8

"Ó bu omi mu ara rẹ̀ sí yà. Ó wa wo àyíká láti rí dájú pé ẹnìkankan kò wó òun.

Mbom mú òkúta kan, ó sì jú s'ínu ómi. Ó wòó bí ó ti rú gọ́gọ́, tí ó sì túká. Ó tẹ lọ́rùn, ó sì mú igi. Ó jù sínu rẹ̀. Ohun kan náà ni ó tún sẹlẹ̀."

9

"Mbom sí fò sí inú omi náà! Ó nírètí iyè àinípẹ̀kun. Bí ó ti fò sínu rè, odò náà dìde s'òkè. Ó sì fò lọ ṣí sánmọ̀, kò sì padà sí Mbadede láilái. Sùgbọ́n ní ìgbà míràn, òsùmàrè má ń tẹ̀lé òjò láti mọ̀ọ́ lára bí odò padà.

Níbè ni ìtàn mí parí sí," Íyá wí.

10

"Wàyí ò̀ ẹ̀yin àyànfẹ́, kí ló dé tí ẹ fẹ́ran ìtàn yìí gan?" Ìyá bèrè. "Ẹ má ń bèrè ki n sọ́ọ ní ọ̀pọ̀ ìgbà."

"Mo fẹ́ràn rẹ̀ nítorí ó rán mí létí láti ma kíyèsí ìfura mi," Udoo rín ẹ̀rín.

"Ó rán mí lọ́wọ́ láti ránti àwọn àwọ̀ òsùmàrè," Erdoo fikun.

11

Eryum náà gbíyànjú ti rẹ̀, "Mo fẹ́ràn rẹ̀ nítorí ó rán mi létí aísìkirimù! Sé mo lè rí díẹ̀ nísìnsíyìí, ẹjọ̀wọ́?"

"Mmmm. Otútù ń mú nísìnsíyìí, jẹ́ kí á jẹ aísìkirimù ní ọ̀la. Àbí?" Ìyá wí. Wọ́n sì fikun, "Nígbà míràn, mà a sọ ìtan òpin òsùmàrè."

12
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Odò òsùmàrè onídán
Author - Mimi Werna
Translation - Ọmọniyì Olúwabùkọ́lá
Illustration - Edwin Irabor
Language - Yoruba
Level - Longer paragraphs