Ìdí Tí Wọn Kò Sin Ajao
Taiwo Ẹhinẹni
Jesse Breytenbach

Ajao, àdán kan, sùn sí ilé rẹ̀ nínú àárẹ̀. Kòsí ẹnikẹ́ni tí ó yojú sí i.

1

Lẹ́yìn náà, Ajao kú.

2

Àwọn aládùúgbò ní, "Ajao ti kú, a gbọdọ̀ pe àwọn ẹbí rẹ̀ láti wá sín."

3

Àwọn aládùúgbò lọ pe àwọn ẹyẹ pé, "Ìkan lára yín ti kú."

4

Àwọn ẹyẹ wá, wọ́n sì ri pé Ajao ni. Wọ́n ní, "Ẹranko yìí kì í ṣe ara ẹbí wa."

5

"Gbogbo ẹbí wa ní ìyẹ́ ṣùgbọ́n Ajao kò ní nǹkankan. Nítorí náà, kì í ṣe ara wa." Àwọn ẹyẹ náà sálọ.

6

Àwọn aládùúgbò ronú papọ̀, wọ́n ní, "Òòtọ́ ni àwọn ẹyẹ sọ. Ajao kò ní ìyẹ́. Nítorí náà, kì í ṣe ara wọn."

7

Ìkan lára wọn ní, "Ó gbọdọ̀ jẹ́ ìkan lára àwọn eku. Ó jọ wọ́n."

8

Àwọn aládùúgbò lọ pe àwọn eku pé, "Ìkan lára àwọn ẹbí yín ti kú."

9

Àwọn eku wá, wọ́n sì ri pé Ajao ni. Wọ́n ní, "Ẹranko yìí kì í ṣe ara ẹbí wa."

10

"Gbogbo ẹbí wa ní ìrù ṣùgbọ́n Ajao kò ní ìrù." Àwọn eku náà rìn lọ.

11

A kò rí ẹbí fún Ajao, ó sì wà bẹ́ẹ̀ láì sí ẹni tí yóò sín in.

12
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ìdí Tí Wọn Kò Sin Ajao
Author - Taiwo Ẹhinẹni
Illustration - Jesse Breytenbach
Language - Yoruba
Level - First sentences