Ọjọ́ Tí Òòrùn Rin Ìrinajò
Khothatso Ranoosi
Jesse Breytenbach

Òòrùn pinnu láti lọ kí àbúrò rẹ̀ obìnrin, òṣùpá. Òṣùpá ń gbé ní òdìkejì òfuurufú. 'Mo máa padà dé láìpẹ́, Òòrùn sọ fún ìkuukù.

1

Kò pẹ́ tí Òòrùn jáde lọ, àwọn òkè wé gèlè funfun.

2

Afẹ́fẹ́ ń ṣàríyànjiyàn pẹ̀lú àwọn igi. Inú bí àwọn igi. Wọ́n fọ́n gbogbo ewé wọn ká ibi gbogbo.

3

Òfuurufú bẹ̀rẹ̀ sí i kùn. Ó yírá padà sí òféèfé.

4

Inú àwọn ìkuukù kò dùn láti rí ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Ẹkún púpọ̀ wà.

5

Gbogbo àgbáyé bẹ̀rẹ̀ sí í rì wọnú omi lọ.

6

Bẹ́ẹ̀ kẹ̀dẹ̀ ré, ní apá kejì òfuurufú, Òòrùn ti ṣetán láti kúrò lọ́dọ̀ àbúrò rẹ̀. Wọ́n fẹnu konu, ó kí òṣùpá pé ó dìgbà ó sì padà sí ilé.

7

Inú òfuurufù dùn púpọ̀ láti rí Òòrùn tó bẹ́ẹ̀ tí ó sì yípadà sí àwọ̀ búlù. Àwọn òkè wọ àsọ aláwọ̀-ewé wọn.

8

Afẹ́fẹ́ lọ sùn. Awọn igi na ẹ̀ka wọn, wọ́n sì rẹ́rìn-ín.

9

Inú àwọn ìkuukù dùn láti rí Òòrùn padà. Wọ́n jádé lọ ṣeré.

10

Ọ̀pọ̀ àwọn ewéko kéèkèèké hù jáde láti inú ilẹ̀ láti ṣe " báwo ni?" Gbogbo àgbáyé ń tàn yinrin.

11

Òòrún tan ìtànṣán rẹ̀ sí ibi gbogbo. Pẹ̀lú ayọ̀, ó ní "Mo wí fún yín pé n óò padà wá."

12
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ọjọ́ Tí Òòrùn Rin Ìrinajò
Author - Khothatso Ranoosi, Marion Drew
Translation - Ṣẹ́gun Ṣóẹ̀tán
Illustration - Jesse Breytenbach
Language - Yoruba
Level - First sentences