Ní ìgbà kan, Ìjàpá àti Ọ̀kẹ́rẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́. Ní ọjọ́ kan lẹ́yìn oúnjẹ, Ọ̀kẹ́rẹ́ bi Ìjàpá, "Ọ̀rẹ́ mi, ọjọ́ ọjà ti fẹ́ dé ṣùgbọ́n a kò ní owó. Irú iṣẹ́ wo ni a lè ṣe láti pa owó?"
1
Ìjàpá dáhùn, "Ṣé o mọ̀ pé mo máa ń ṣe abọ́. Mo fẹ́ kí o wá sílé mi kí a jọ̀ ṣe àwọn abọ́ púpọ̀ tí a lè tà." "Ó dáa ọ̀rẹ́ mi, a ó pàdé lọ́la láti ṣe àwọn abọ́ náà," Ọ̀kẹ́rẹ́ dáhùn.
2
Ní ọjọ́ ọjà, Ìjàpá lọ sí ọjà. Ó rí àwọn méjì ní ọ̀ọ́kán tí wón ń jà. Kíá, ó gbé àwọn abọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ síbi ìjà náà.
3
Nígbà tí ó débẹ̀, ó ri pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ Ọ̀kẹ́rẹ́ ni ó ń jà pẹ̀lú Ẹmọ́.
4
Níkété tí ó débẹ̀, láì wádì oun tí ó fa ìjà náà, Ìjàpá mú igi ńlá o sì bẹ̀rẹ̀ sí ní í na Ẹmọ́. "Fi ọ̀rẹ́ mi sílẹ̀!" Ìjàpá kígbe.
5
Lẹ́hìn náà, Ẹmọ́ dojúkọ Ìjàpá ó sì bu imú rẹ̀ jẹ.
6
Imú Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣẹ̀jẹ̀.
7
Ìjàpá ti bẹ́ sínú ìjà Ọ̀kẹ́rẹ́ àti Ẹmọ́ láìronú. Láti ọjọ́ yìí ni imú Ìjàpá ti rí kọ́ńbó tí ó kọ́ wa pé àìfara balẹ̀ kò dára.
8
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Bí Imú Ìjàpá Ṣe Rí Kọ́ńbó
Author - Taiwo Ẹhinẹni Illustration - Marleen Visser Language - Yoruba Level - First paragraphs