Ilé Luwo
Little Zebra Books
Jacob Matthess

Luwo lo sílé ìjósiǹ pèlú iyá re.

Ìyá re di owó re mú lójú ònà.

1

Nínú ilé ìjósiǹ, awon èrò púpó péjò.

Won nkorin.

2

Luwo fi ilé ìjósiǹ sílè.

Ìyá re ko ri.

3

Luwo dúró sójú ònà.

Ó wo òjú ònà, ó ronú, "Ilé mi da?"

4

Ó gba ojú óná naa. Ó rí ilé ńlá kan.

"Rárá o, ilé wá kó nìyí. Ilé wa kéré."

5

Luwo rìn síwájú díè si. Ó ri ilé lórí òpó.

"Rárá o, ilé wá kó nìyí, ilé wa kò sí lórí òpó."

6

Ó si ǹtesíwájú. Ó rí ilé kékeré tí a fi koríko Alámò kó.

"Rárá o, ilé wá kó nìyí. Ilé wa ní ogìri Alámò."

7

Luwo rìn jìnnà. Ó rí ilé kékeré tí igi wa níwáju re.

"Rárá o, ilé wá kó nìyí. Igi méjì ló wà níwájú ilé wa."

8

Nígbàtóyá Luwo ri ìyá re tó nbò wá sódò re. Luwo sáré sii.

Iya re wípé, "Jé ká lo sílé!"

9

Ewo ni ilé Luwo?

10
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ilé Luwo
Author - Little Zebra Books
Translation - Esther Chibuzor, Meweabi Raji
Illustration - Jacob Matthess
Language - Yoruba
Level - First sentences