

Fati jẹ ọmọbirin kekere kan ti o n sare bi afẹfẹ.
O fẹràn lati rẹrin, nigbagbogbo o gbiyanju gidigidi lati ma gbọnran.
Ni ọjọ kan, Fati lọ pẹlu iya ati baba rẹ lati wa igi idana.
Fati fẹran lati ṣe iranlọwọ fun iya ati baba rẹ, ṣugbọn pupọ wa lati ṣe ati pupọ lati rii.
Awọn ẹiyẹ, awọn ọbọ, ati awọn ọrun wa nibẹ!
Iya sọ pé, "Fati, jọwọ gbọ! O le wa igi idana ni ibi, o si le wa a ni ibe yen."
"Ṣugbọn Fati, jọwọ wo ibiti o lọ ki o ṣọra gidigidi."
O si dahun pe, "Bẹẹni, iya."
Laipẹ, iya ati baba Fati n ṣiṣẹ takuntakun.
Wọn ri awọn igi igi-ina nla.
Wọn ri awọn igi- idana kékéré.
Fati tun nšišẹ gidi-gidi.
O ri awọn igi idana kékéré die.
O si ri awọn igi idan ti o kéré pupo.
Lẹhinna, Fati wo oke.
O rii eye pupa ninu koriko giga.
Lẹhinna, Fati wo isalẹ.
O wo kokoro alawo burawun lori oju opo.
Fati ri ewe ti o lẹwa. Ewé náà n dan o si ni awo ewé.
O fi ika kan sori ewe ti o lẹwa.
Fati sọ pe, "Eyi ko ri bi ewé."
Lojiji, ewe ti o lẹwa naa gbe ra!
Fati sọ pe, "Eyi kii ṣe ewe ẹlẹwa. Ejo alawọ ewe ni yii!"
Fati pariwo, "Eii!"
O yara yara lati wa iya ati baba rẹ.
Fati rii baba rẹ o kigbe, "Ejo! Ejo!"
Baba ni, "Nibo? Nibo ni?"
Fati sọ pe, "O wa nibẹ yen!"
Lẹhinna baba rẹ lepa ejò alawọ ewe naa.
Ejo alawọ ewe fa lo.
Bàbá sọ pé, "Fati, o wa ni alafia. Jẹ ki a lọ ba iya re, ki o le sọ nipa ejò alawọ ewe."
Iya sọ pe, "Fati, Inu mi dun pe ejò alawọ ewe naa ko san o jẹ."
"Ṣugbọn nigba miiran, jọwọ, wo ibiti o lọ, ki o ṣọra diẹ sii."
Ati pe lo ba tan.

