Ọba Burúkú Kan
Alice Nakasango
Marleen Visser

Ní ayé àtijọ́, ewúrẹ́ jẹ́ ọba àwọn ẹranko àti ẹyẹ. Ó pe ìpàdé kan.

1

Ewúrẹ́ sọ fún àwọn ẹranko pé òun lá àlá. Gbogbo àwọn ẹranko tẹ́tí sí i.

2

Àlá náà wà nípa ebi.

"Ólógbò bèèrè pé "Kí la máà ṣe?"

3

Adìyẹ àtí Pẹ́pẹ́yẹ ní, "Ẹ jẹ́ ká tọ́jú oúnjẹ púpọ́ sí àgbàlá ọba

4

Ewúrẹ́ tí ó jẹ́ ọba àwọn ẹranko ní, "Ẹ so ẹnikẹ́ni tí kò bá tẹ̀lé òfin."

5

Àsìkò tó láti yan ọba tuntun.

Wọ́n yan ológbò

6

Ewúrẹ́ kò fẹ́ kí ológbò jẹ ọba. Ó ní, "èmi ni ọba."

7

Ewúrẹ́ kò kó oúnjẹ.

Màálù bèèrè pé, "Kí lá máa ṣe?"

8

Gbogbo àwọn ẹranko sọ̀rọ̀ papọ̀

Inú bí gbogbo sí ewúrẹ́

9

Ajá ní, "Mo dúró tìí ní gbogbo ìgbà tí ó jẹ́ ọba."

10

àgùtàn ní, "Mó fún àwọn ọmọ rẹ̀ ní irun mi."

11

Ẹlẹ́dẹ̀ pariwo, "Nígbà tí ó jẹ́ ọba, mó báa tọ́jú ọgbà rẹ̀."

12

"Ṣé ewúrẹ́ rò pé òun máa jẹ́ ọba títí ayé ni?" Àgùtàn bèèrè.

13

Awọn ẹranko fẹnukò pé ewúrẹ́ gbọ́dọ̀ gbé oúnjẹ lọ fún ológbò, ọba wọn

14

Àwọn ẹranko lọ bá ewúrẹ́. Ewúrẹ́ ní, "Mo máa jẹ́ ọba títí láé láé."

15

"A máa dè ẹ lókùn ká tó gbé ẹ lọ sọ̀dọ̀ ọba tuntun."

16

Màálù wọ́ ewúrẹ́ lọ sí ààfin ọba.

Inú gbogbo àwọn ẹranko dùn.

17

Ìdí nìyìí tí ewúrẹ́ fí máa ń takú nígbà tí wọ́n bá fàá.

18
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ọba Burúkú Kan
Author - Alice Nakasango
Translation - Olusegun Soetan
Illustration - Marleen Visser
Language - Yoruba
Level - First words