

Ní ọ̀pọ̀ ìgbà sẹ́yìn, ọkùnrin kan wà tí à ń pè ní Kàtó. Ó ń gbé ní ìlú Kábúùsù. Ó ń gbé pẹ̀lú ajá ẹ̀ nínú ilé kékeré.
L'ọ́jọ́ kan, ara Kàtó ò yá. Kò ní olùrànlọ́wọ́ kankan. Nígbà tí ara rẹ̀ yá, ó pinnu láti fẹ́ obìnrin kan tó ń gbé ní tòsí rẹ̀.
Ó f'ìwé pe àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí rẹ̀ láti wá fún ayẹyẹ ìgbéyàwó. Inú Kàtó dùn gan nítorí ó rò pé òun ti rí olùrànlọ́wọ́.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni wọ́n rà fún ọkọ àti ìyàwó. Bí i apẹ̀rẹ̀ jero, ẹní, ọ̀gẹ̀dẹ̀, ẹ̀pà àti àwọn ẹ̀bùn ìmíì fún ilé.
Gbogbo àlejò lọ'lé nígbà tí ayẹyẹ ìgbéyàwó náà parí. Kàtó ti ń gbáradì láti bẹ̀rẹ̀ sí nígbé igbé ayé titun pẹ̀lú aya àti ajá rè
L'ọ́jọ́ èkejì, Kàtó fún ìyàwó rẹ̀ ní ọ̀gẹ̀dẹ̀ jíjẹ àmọ́ kò jẹ ẹ́.
Nígbà tí Kàtó lọ ṣe ìgbẹ́ dídẹ, obìnrin yìí jẹ gbogbo ọ̀gẹ̀dẹ̀ jíjẹ náà.
Ebi ń pa Kàtó nígbà tí ó dé láti ibi tí ó ti lọ gbe idẹ. Ó bèèrè ọ̀gẹ̀dẹ̀ jíjẹ. Ìyàwó rẹ̀ sọ pé ajá ti jẹ gbogbo ẹ.
Kàtó lọ sí oko rẹ̀ l'ọ́jọ́ èkejì. Nígbà tí ó dé'lé, ó rí i pé ìyàwó rẹ̀ ti jẹ gbogbo ẹran. Kò ti ẹ̀ pin pẹ̀lú ajá náà.
L'ọ́jọ́ ìmíì, Kàtó lọ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nígbà tí ó máa fi dé, obìnrin yìí ti jẹ gbogbo ẹ̀pà. Apẹ̀rẹ̀ náà ṣófo pátápátá. Kàtó sì bínú sí ìyàwó tuntun rẹ̀.
Kàtó rò ó pe "Nǹkan ń ṣe obìnrin yìí." Ó pinnu láti lo jùjú. Ó fi mílíìkì sínú ìkòkò jùjú náà, ó gbe sí abẹ́ bẹ́ẹ̀dì ó sì lọ de ìgbé.
Nígbà tí obìnrin yìí rí ìkòkò tó kún fún mílíìkì. Lógán, ni ó gbé ìkòkò náà s'ẹ́nu. Bí ajá ti ń wò ó ni ó sẹ mu gbogbo mílíìkì náà tán.
Ó ṣe'ni l'áàánú pé ìkòkò gan mọ l'énu. Ó gbìyànjú láti fà á yọ àmọ́ pàbó ló jásí. Ó pariwo, ó fò s'ókè s'ódò àmọ́ ìkòkò náà gan mọ́ ibẹ̀. Ajá náà ń wo gbogbo ẹ.
Ajá náà sáré lọ wá Kàtó. Ó gbó, gbó, ó fò s'ókè s'ódò. Kàtó.fura pé nǹkan ti ṣẹlẹ̀ n'ílé.
Wọ́n sáré lọ ilé papọ̀. Ìyàlẹ́nu ni ó jẹ́ fún Kàtó nígbà tí ó rí pé ìkòkò ti gan mọ́ ìyàwò rẹ̀ l'énu. Ó wò ó, ó sì tún yà á l'ẹ́nu.
Kàtó fi ọwọ́ kan ẹ̀kẹ́ ìyàwó rẹ̀, ìkòkò náà sì jábọ́ l'ẹ́ẹ̀kan náà. Ojú ti obìnrin náà. Ó pinnu láti padà lọ sí ilé àwọn òbí rẹ̀.

