

Ní ayé àtijọ́, ní ààfin-ọba kan, ọba kan wà tí ó ní ọmọbìnrin awẹ́lẹ́wà kan.
Eerin ń gbé ni ilé kan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààfin. Ọ̀gà ń gbé ní ilé mìíràn ní òdìkejì ààfin.
Ní àkókò yìí, ọ̀gbẹlẹ́ kan wà ní gbogbo ilú. Èrò kan sọ sí ọba nínú ó sì pe àwọn aládùúgbò mejèèjì sí ààfin.
Ọba náà wí fún Eerin àti Ọ̀gà pé " mo fẹ́ kí ẹ máa fi ẹsẹ̀ janlẹ̀ títí omi yòó fi rú jádé." Ọba ṣe ìlèrí láti fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ṣe àṣeyọrí.
Ọ̀gà kò ní ìrètí nítorí pé ó kéré púpọ̀. Inú Eerin dùn púpọ̀ nítorí pé ó tóbi ó sì ní agbára. Eerin lọ sí orí ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ẹsẹ̀ janlẹ̀.
Eruku bo ilẹ̀, ṣùgbọ́n omi kò jáde. Eerin fi ẹsẹ̀ janlẹ̀ títí omi fi fẹ́ bẹ́rẹ́ sí i sun jáde, ṣùgbọ́n ó ti rẹ̀ ẹ́. Ó fún Ọ̀gà ní àyè láti gbìyànjú.
Ọ̀gà bẹ̀rẹ̀ sí fí ẹsẹ̀ janlẹ̀. Láìpẹ́, omi sun jáde. Ẹnu sì ya àwọn ènìyàn!
Nítorí náà, ọba fi ọmọbìnrin rẹ̀ fún Ọ̀gà láti fẹ́. Eerin sì lọ si ilé rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú.

