Anansi Àti Ìjàpá
Ghanaian folktale
Wiehan de Jager

Ní ọjọ́ kan, Anansi aláǹtakùn mú àwọn iṣu láti ọgbà-oko rẹ̀. Àwọn iṣu aládùn kù, nítorí náà ó dín wọn dáradára lórí iná. Lẹ́hìn náà, ó jòkó láti jẹ wọ́n.

1

Bí Anansi ṣe fẹ́ jẹ́ iṣu àkọ́kọ́, ó gbọ́ pé ẹnikan kan ilẹ̀kùn rẹ́. "Rárá o!" Anasi ronú. "Ta ni ó lè jẹ́?" Ṣùgbọ́n ó ṣí ilẹ̀kùn rẹ̀. Níbẹ̀ ni Ìjàpá, ó rí bí i ẹni tí ó rẹ̀ púpọ̀. Ìjàpá ní, "Anansi, jọ̀wọ́ jẹ́ kín wọlé. Mo ti rín jìnà lónìí, ó tí rẹ̀mi àti wípé ebi ń pámi." Nítorí náà kí ni Anansi le ṣe ju kí ó jẹ́kí ó wọ́lé.

2

Anansi ní ahun gan an ni débi pé kò lè fún ẹnikẹ́ni jẹ lára iṣu aládùn rẹ̀. Nítorí náà, ó ṣe ìpinu kan. Ní Ìjàpá ṣe jòkó sí orí tábìlì tí ó fẹ́ fọwọ́ kan àwọn iṣu rẹ̀. Anansi pariwo mọ́, "Ìjàpá, ọwọ́ rẹ̀ ti dọ̀tí jù! O kòlè jẹun pẹ̀lú dídọ̀tí yìí! Lọ fọ ọwọ́ rẹ̀." Ọwọ́ Ìjàpá dọ̀tí ní tòótọ́. Nítorí náà, ó wọ́ lọ sí odò, fọ ọwọ́ rẹ̀, ó sì wọ́ padà.

3

Ṣùgbọ́n Anansi ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó gbogbo àwọn iṣu náà jẹ. Nígbà tí Ìjàpá fi padà, ó ri pé gbogbo àwọn iṣu náà ti lọ. Ìjàpá wo Anansi. "Ó ṣé tí o pè wá fún oúnjẹ alẹ́. Tí o bá wá sí ilé mi, jọ̀wọ́ wọ́lé kín lè san ore yìí padà fún ẹ," Ìjàpá dáhùn. Ìjàpá sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ́ lọ sí ilé rẹ̀.

4

Lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò, Anansi bẹ̀rẹ̀ sí ronú bí Ìjàpá ṣe pinu láti fún ní oúnjẹ alẹ́. Nítorí náà, ní ọjọ́ kan, ó lọ sí ilé Ìjàpá. Anansi dé ilé Ìjàpá ní àkókò oúnjẹ́ alẹ́, bí oòrùn ṣe ń múra láti wọ̀. Ìjàpá sùn sí orí àpáta, ó ń ṣeré, bí àwọn Ìjàpá ṣe máa ń ṣe. Nígbà tí Ìjàpá rí Anansi, ó ní, "Báwo ni, Anansi, ṣé o wá láti jẹ oúnjẹ alẹ́ pẹ̀lú mi ni?" Anansi sì sọpé, "Bẹ́ẹ̀ni, èyí dára púpọ̀, o ṣé." Ebi sì bẹ̀rẹ̀ sí i páa.

5

Nítorí náà, Ìjàpá wọ inú odò lọ sí ìsàlẹ̀ láti lọ ṣètò ṣílẹ̀ fún oúnjẹ́ alẹ́ náà. Anansi dúró ní orí àpáta lẹ́bàá odò. Láìpẹ́ Ìjàpá wẹ̀ wá sí òkè orí omi, o ní "Óyá Anansi, gbogbo nǹkan ti wà nílẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí a jọ̀ jẹun." Ìjàpá wẹ̀ padà lọ sí ìsàlẹ̀ láti lọ bẹ́rẹ́ sí ní jẹ àwọn ewé tí ó ṣètò fún oúnjẹ.

6

Anansi gbìyànjú láti wọ inú odò lọ sí ìsàlẹ̀, ṣùgbọ́n aláńtakùn ni kì í ṣe Ìjàpá, kò lè wẹ̀ sísàlẹ̀. Ó kan dúro sí ojú omi ni. Ó gbìyànjú láti bẹ́ sínú odò náà, ó gbìyànjú láti wọ odò náà, ṣùgbọ́n ó kùnà. Kò lè lọ̀ ìsàlẹ̀ lọ sí oúnjẹ́ náà.

7

Lẹ́hin náà Anansi ní àbá kan. Ó kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkúta sí àpò rẹ̀. Èyí mú kí ó wá wúwo láti lè wọ̀ inú odò. Ó mà gbọ́n gan an ni o! Ó rí tábìlì Ìjàpá, tí ó kún fún àwọn ewé aládùn àtí ọ̀pọ̀lọpọ oúnjẹ dídún. Ẹnu Anansi bẹ̀rẹ̀ sini pòǹgbẹ́ oúnjẹ yìí.

8

Bí Anansi ṣe fẹ́ mú lára oúnjẹ yìí, Ìjàpá dadúró. O ní "Anansi, dájúdájú ó kò ní fẹ́ jẹun pẹ̀lú aṣọ rẹ̀? Kì í ṣe bí a ṣe máa ń ṣe nǹkan ní ilé mi." Anansi, láí ronú, ní, "Bẹ́ẹ̀ni, òótọ́ lo sọ, Ìjàpá, kí ni mo ń rò?" Ó bọ́ aṣọ rẹ̀.

9

Ṣùgbọ́n láí sí àwọn òkúta ní àpò rẹ̀ láti mu dúró sí ìsàlẹ̀ odò náà, omi gbé Anansi lọ sí ojú omi padà. Anansi fi ojú rẹ̀ sínú omi, o sì rí bí Ìjàpá ṣe jẹ gbogbo aládùn náà.

10
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Anansi Àti Ìjàpá
Author - Ghanaian folktale
Translation - Taiwo Ẹhinẹni
Illustration - Wiehan de Jager
Language - Yoruba
Level - Longer paragraphs