Ọba wá ọkọ fún ọmọ-ọba
John Emongot
Catherine Groenewald

Ni aye atijọ, ọba kan wa ti orukọ re n je Opale. Oba Opale ati arẹwa iyawo re bi ọmọ obinrin kan soso.

1

Ni ọjọ kan, ọba ripe ọmọ re ti balaga, O si sọ fun iyawo rẹ pe '' akoko ti to ki ọmọ ọba lọ si ile ọkọ. A gbọdọ wa arẹwa ọkunrin kan lati ilu wa fun".

2

" Talo ma fẹ ọmọ mi? ọba sọ lọkan rẹ. Ọba pinu lati dan awọn ọmọkunrin ti o ba fẹ fẹ ọmọọba wo. "Mo ma gbe omi kana, ti o ba ti ho daadaa, ẹnikẹni ninu awọn ọmọkunrin ti o ba le gbe omi gbigbona yi mu, ni yi o fẹ ọmọọba.

3

Ni ojo keji, oba ṣe ikede wipe ki gbogbo omokunrin ti ko ba ti ni iyawo wa si aafin.

Kere o! Kere o!
gbogbo eyin omokunrin ti ko ba ti ni iyawo sile, oba n wa oko fun omooba. ///ki gbogbo yin wa si aafin ọba o!

4

Inu awọn ọmọkunrin ilu yi dun gidi, nigbati wọn gbọ ikede ọba, gbogbo wọn si mura lati lọ si aafin ni ọjọ keji.

5

Ọmọ ọkunrin kan sọ fun baba re, mo gbọ wipe ọba ti pe gbogbo awọn ọmọkunrin ilu wa si aafin, lati le wa ọkọ fun ọmọọba. "baba mi, mo gbọdọ lọ si iwaju ọba ni aafin, o da mi loju wipe mo ma padawa pelu ọmọọba.

6

Ni ọjọ keji, awọn ọmọọkunrin ilu wọ aṣọ ti o jọju lọ si aafin ọba. Inu wọn si n dun yin.

7

Nigbati wọn de aafin, ọba ki wọn kaabọ. Ọba si wipe, 'ẹnikẹni ninu yin ti o ba le gbe ikoko omi gbona yi mu lẹkanṣoṣo, lo ma fẹ ọmọọba'.

8

Awọn ọmọkunrin ilu ti o gbiyanju lati gbe ikoko omi gbigbona yi mu, pọ to jẹ wipe, ṣugbon gbogbo akitiyan wọn, pabo lo jasi.

9

Ni ọjọ keji, ehoro ti ko tete gbọ ikede ọba wa si aafin. Wọn ki kaabo, wọn si ni ki o joko.

10

Ọba si sọ fun wipe, ẹnikẹni ti o ba fẹ fi ọmọọba ṣe aya, gbọdọ gbe ikoko omi gbigbona yi mu lẹkanṣoṣo. Ehoro si daahun wipe, nkan kekere ni eyi jẹ fun ohun.

11

Ọgbọn arekereke pọ lọwọ ehoro. O bẹẹrẹ alọ alaarin kan fun ọba. Alọ yi lọba tẹti si, titi ti omi gbigbona fi tutu.

12

Inu ọba ati awọn ijoye dun pupọ. Laarin iṣẹju diẹ, ehoro si gbe ikoko omi yi mu.

13

Oya Ọba ati awon ijoye lẹnu wipe, ehoro da ikoko omi yi mu lẹkanṣoṣo, ti ko si jo lẹnu.

14

Bayi ni ehoro ṣe fẹ ọmọọba tẹrin tẹrin, ṣugbọn inu ọba ko dun nitoripe ẹranko lasanlasan ni o papa fẹ ọmọọba.

15
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ọba wá ọkọ fún ọmọ-ọba
Author - John Emongot
Adaptation - Temi Ola
Illustration - Catherine Groenewald, Wiehan de Jager, Caroline Lentupuru, Laura Libertore, Benjamin Mitchley
Language - Yoruba
Level - Longer paragraphs