Kò Sí Ẹni Tó Ní Gbogbo Ọgbọ́n
Emmanuel Anglican Church
Indiana University Books & Beyond Project

Ìtàn yìí dá lórí Ìjàpá àti Ìgbín
ìjàpá jẹ́ ẹranko tó ní ọgbọ́n púpọ̀.

Ó sì gbàgbọ́ pé òun gbọ́n ju gbogbo àwọn ẹlòmíràn lọ.

1

Ó sọ wí pé òun fẹ́ kó gbogbo ọgbọ́n jọ, kí ó sì fi sínú kèrègbè kan.

Ó gbèrò láti gun igi gíga kan, kí ó sì fi kèrègbè náà pa mọ́ sí orí igi náà, kí ẹlòmíràn má lè ní ọgbọ́n to.

2

Ìjàpá ń rìn kiri, ó ń wa igi tí yó gbé kèrègbè rẹ̀ sí, ṣùgbọ́n igi àkọ́kọ́ tí ó rí kúrú.

3

Ó rí igi mìíràn, igi náà kúrú gan.

4

Ìjàpá rí igi kẹta tí ó ga gan, igi yìí jẹ́ igi tí ó dára láti gbé ọgbọ́n rẹ̀ pamọ́ sí.

5

ìjàpá bẹ̀rẹ̀ si ní gun igi náà, ó ti so kèrègbè ọgbọ́n mọ́ àyà. Ṣùgbọ́n, kèrègbè náà ń di lọ́wọ́ bí ó ṣe ń gun igi náà.

6

Ìgbín ń kọjá lọ nígbà tí ó ṣàkíyèsí pé ìjàpá kò rí igi náà gùn nítorí kèrègè tí ó wà nígbà àyà rẹ̀. Ìgbín bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni ìṣòro tí ó ń ní. Ìjàpá dáhùn pé kèrègbè tí gbogbo ọgbọ́n òun wà nínú rẹ̀ kò jẹ́ kí òun lè gun igi náà.

7

Ìgbín sọ fún ìjàpá pé kí ó so kèrègbè náà mọ́ ẹ̀yìn rẹ̀ dípò àyà. Nígbà náà ni ìjàpà tó rí igi náà gùn.

8

Bí ìjàpá ṣe ń sọ̀kalẹ̀ láti orí igi náà, ní ohùn kan sọ fun pé.

9

Bí ìgbín bá lè fún òun ní ìmọ̀ràn tí ó rọrùn tí ó sì wúlò, ó túmọ̀ sí pé kò sí ẹni tí ó ní gbogbo ọgbọ́n.

10
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Kò Sí Ẹni Tó Ní Gbogbo Ọgbọ́n
Author - Emmanuel Anglican Church, Indiana University Books & Beyond Project
Illustration - Indiana University Books & Beyond Project
Language - Yoruba
Level - First paragraphs