

ìtàn yìí dá lórí ìjàpá àti ìgbín. Ìjàpá jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ, ó sì ní ọgbọ́n àrékérekè, ó gbọ́n tinú-tẹ̀yìn, èyí máa ń mu kí ó sọ wí pé òun ní ọgbọ́n ju gbogbo ènìyàn lọ.
Èyí mu kí ó mú gbogbo ọgbọ́n tí ó ní, ó gbé gbogbo rẹ̀ sínú akèrègbè, ó sọ wí pé òun yóò gbe pamọ́ sí orí igi.
Bí ó ti sẹ ń lọ ni ó tajú kán, ó rí igi àkọ́kọ́, ó sọ fún ara rẹ̀ wí pé, igi náà ti kéré jù, ó rí igi kejì, ó tún sọ fún ara rẹ̀ wí pé ó ti kéré jù, bí ó ti ṣe rí igi kẹta ni inú rẹ̀ dùn wí pé igi náà ga púpọ̀, yòó sì wúlò fún òun láti lè fi ọgbọ́n òun pamọ́ sí orí rẹ̀.
Bí ó ṣe ń gun igi náà ni akèrègbè ọgbọ́n rẹ̀ wà ní igbáàyà rẹ̀, èyí kò fún ní àǹfàní láti gun orí igi náà, bí ó ti ń gùn-ún ni ó ń jábọ́, ó sì tí kó gbogbo ọgbọ́n sí nú akèrègbè.
Bí èyi ṣe ń wáyé ni ìgbín kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó ṣàkíyèsí wí pé kò rí igi náà gùn, ìgbín bèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kí ni ó ṣe é tí ó ń rábàbà lójú kan, ni ìjàpá bá da lóhùn pé akèrègbè ọgbọ́n òun ni kò fún òun láyè láti rí igi náà gùn.
ìgbín sọ fun wí pé kí ó tún igi náà gùn, bí ó ti ń gbìyànjú rẹ̀ lọ́wọ́ ni ìgbín sọ fun wí pé kí ó gbé akèrègbè náà sẹ́yìn kí ó wá gun igi náà lẹ́ẹ̀kan si.
Gbàrà ni ìjàpá gun igi náà dókè, bí ó ti ń bọ̀ lẹ́ ló rí igi náà ni ìgbín sọ fun wí pé kí ó gbé akèrègbè náà sẹ́yìn. lẹ́ẹ̀kan náà ni ìjàpá sọ wí pé, à ṣé kò sẹ́ni tí ó gbọ́n tán.
Ẹ má má jẹ́ kí a rí ara wa bí ẹni tí ó gbọ́n jù.

