Itan Kẹta - Àkọ́lé: Owú jíjẹ
Tba Tba
Tba Tba

Orin - Ìkà ò pé
Ẹ má ma ṣé
Ìkà ò pé, ẹ má ma ṣé o
Rere ló pé, ara mi

1

Ìtàn náà dá lé lórí orogún méjì, ìyálé ṣabiamọ, ìyàwó náà ṣabiamọ. Ọkọ wọn lówó, ó ń tọ́jú àwọn méjèjì, kò sí nǹkan tí wọ́n fẹ́, tí ọkọ wọn kò fi tẹ́ wọn lọ́rùn, ṣùgbọ́n bí ọkọ ṣe ń tẹ́ gbogbo wọn lọ́rùn, inú ìyálé kò dùn si ọmọ ìyàwó mọ̀wé

2

ju ọmọ òun lọ, kò mọ̀ wí pé, ilé ayé kò rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé ohun gbogbo wà lọ́wọ́ Elédùmare.

3

Bí ènìyàn bá ní sùúrù, ohun tí kò tó ń bọ̀ wá ṣẹ́kù, nítorí pé ìyálé kò ní èrò tó da, gbogbo ọ̀nà ni ó ń wá láti pa ọmọ ìyàwó nítorí pé ọmọ ìyàwó mọ̀wé ju ọmọ t'òun lọ.

4

Ìyálé kò ní àròjinlẹ̀, bí gbogbo wọn ti jáde ni ìyálé se àsáró, ó se èyí tí ó rẹ̀ dòdò pẹ̀lú epo àti èyí tí ó funfun báláhú, nígbà tí àwọn ọmọ náà ti ilé ìwé dé, ọmọ ìyálé ni ó ṣíwájú, bí

5

ó ti rí àsáró tí ojú rẹ̀ rẹ̀dòdò, ni ó bá jẹ ẹ́, tí ọmọ ìyáwó sì jẹ èyí tí ó funfun báláhú, nígbà tí àwọn méjèjì jẹun tán ni ọmọ ìyálé bá figbe ta, inú bẹ̀rẹ̀ si ni run-ún, ṣùgbọ́n ọmọ ìyàwó kò sí ní ìtòsí nítorí pé ó wà níbi tí ó ti ń gbá

6

bọ́ọ̀lù, nígbà tí wọ́n ma fi wọlé, òkú ọmọ ìyálé ni wọ́n bá nítorí wí pé ìyálé ti fi májèlé sínú àsáró náà lérò wí pé ọmọ ìyàwó ni ó máa jẹ ẹ́, nígbà tí

7

àwọn òbí náà ti ń wọlé bọ̀ ni wọ́n bá ọmọ ìyàwó níbi tí ó ti ń gbá bọ́ọ̀lù, ibẹ̀ ni ará ti fu ú.

8

Bí ó ti wọlé ni ó fara ta pé, òun ti fi ọwọ́ ara òun ṣe ara òun, pé rere ló pé, ìkà kò pé.

9
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Itan Kẹta - Àkọ́lé: Owú jíjẹ
Author - Tba Tba
Illustration - Tba Tba
Language - Yoruba
Level - First paragraphs