

Nílùú kékeré kan, ọmọdé kan wà tí orúkọ ẹ̀ jẹ́ Àkànní. Òbí Àkànní kẹ́ ẹ lákẹ̀ẹ́bàjẹ́ torí òun kò ní ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò; ohunkóhun tó bá fẹ́ lòbí ẹ̀ máa ń fi fún un. Àkànní tìtorí èyí kì í hùwà ọmọlúwàbí. Èyí ló bẹ̀rẹ̀ sí í da òbí ẹ̀ láàmú.
Òbí ẹ̀ kìlọ̀ fún un, kò gbọ́. Àkànní ò gbọ́ràn rárá.
Lọ́jọ́ kan, Àkànní pẹ̀lú ìyá ẹ̀ ń rìn padà lọọlé láti ilé ọlọ́jà nígbà tí Àkànní rí igi máńgòrò. Ó lọ gungi láti ká máńgòrò. Ìyá kìlọ̀ pé "Kúò ńbẹ̀! Má gungi yẹn!"
Àkànní ò gbọ́ ìkìlọ̀ ìyá ẹ̀, ó ṣojú konko tètè gungi. Ó pòṣé mọ́ ìyá ẹ̀, ó ronú pé "A a! Wọn ò fẹ́ fi mí sílẹ̀, màá gbádùn máńgòrò pípọ́n yìí".
Ó ká máńgòrò, ó sì rẹ́rìn-ín. Àyà ìyá ẹ̀ lù kì-kì-kì. Látòkèèrè, ìyá ní "Sọ̀kalẹ̀! Sọ̀kalẹ̀ sẹ́! O ti gbàgbé ẹ̀kọ́ ilé ni? A ò gbọ́dọ̀ jalè". Ìyá sì fara balẹ̀ sọ pé "Màá ra máńgòrò fún ẹ, já á lọ".
Àkànní súfèé, ó dẹ̀ fò láti orí igi. Ó sáré gba ọ̀nà tí ìyá òun kò rí.
"Mi ò gbọ́dọ̀ tọ́ máńgòrò wò torí kí ni?", ni ó ronú bó ṣe jẹ ẹ́. Inú rẹ̀ dun pé òun kò tẹ́tí tí ìyá rẹ̀.
Inú Àkànní ṣàdédé run ún. "Máńgòrò ti bà jẹ́!" Ó dà á nù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe...
Ṣùgbọ́n kò sẹ́nì kankan tó gbọ́ igbe rẹ̀ torí ó ti lọ jìnnàjìnnà sínú igbó. Ó kérora, ó sì rántí ìkìlọ̀ tí òbí rẹ̀ kìlọ̀ fún un.
Ìwà àìgbọràn ò dáa.

