Arugbo Ojo
Ruth Aluko
Magriet Brink

Arugbo Ojo ni Ęni ti Ó da ohun gbogbo àti eniyan. Òun fé kí ènìyàn kí ó mo Òun.

1

Ní ojó kan, Olá ati àbúrò re, Adé n seré ni ìta. Lójijì, Olá rí ohun arewà ti o ni àwò orisirisi ni ojú òrun. O so fun Adé, "Wo oju orun,". N je o mo oruko re?" Ade wipe "Rara". Ola fesi pe "oruko re ni òsùmàrè - ami májèmú Arugbo Ojo".

2

Lojiji, eranko búburú ti o n je, ejò yo si won. Sugbon, Baba Arugbo kan wa, O duro laarin ejo naa ati awon mejeji. Ejo yii sa pada. Ola so fun Ade pe, oruko Baba naa ni Arugbo Ojo; Oun a si ma a pa awon eniyan mo.

3

Baba Arugbo naa so fun awon mejeji pe, "E kede ohun ti eyin ri fun awon elomiran ". Inu Ola ati Ade dun lati se bee.

4

Lehin eyi, awon elomiran ti Ola ati Ade so fun ko ara won jo. Osumare yii si yo si awon naa. Ohun ti awon elomiran yii ri je ki won gbagbo pe otito ni ohun ti awon omo naa so. Inu ti won naa si dun lati so fun elomiran.

5
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Arugbo Ojo
Author - Ruth Aluko
Illustration - Magriet Brink, Offei Tettey Eugene, Leo Daly
Language - Yoruba
Level - First paragraphs