

Àsàkẹ́ jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn. Àwọn ọmọ obìnrin kìí sábà lọ s'ílé ẹ̀kọ́ l'ábúlé wọn.
Òun a máa sisẹ́ ilé nígbàtí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ bá lọ si ílé ẹ̀kọ́.
Ní ọjọ́ kan. Àbúrò bàbá rẹ̀, Onísègùn Òyìnbó wá se àbẹwò sí wọn. Láràba l'órúkọ rẹ̀. Ó wá pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀, Audu ati Binta.
Ariwo gba lẹ́kàn, "ẹkáàbọ̀, ẹkáàbọ̀, Àní Làràba, ẹkáàbọ̀".
Audu béèrè, "Ipele kelòó l'owà n'ílé ẹ̀kọ́,
Àsàkẹ́?" Bàbá rẹ̀ d'alóhùn. Kò sí owó láti rán Àsàkẹ́ nílé èkọ́.
Làràba gbára tá, "ẹ sì lówó láti gbé'yàwó titun?"
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, Láràba mú Àsàkẹ́ lọ sọ́dọ olórí ilé ẹkọ́ láti fi orúkọ sílè.
Pẹ̀lú inúdídùn, Àsàkẹ́ sọ fún ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ pé, "mo ní lọ́kàn láti di Dókítà".
Ọjọ́ kejì ni ilé ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀. Ní àsálẹ́, Àṣàkẹ́ kò leè sùn. Ó yí sọ́tún-ún, ó yí sóósì lóri ibùsùn rẹ. Oorún dá lójú rẹ̀.
Ọkàn rẹ̀ pòrúùru nípa bí ilé ẹ̀kọ́ ṣe máa rí.
Àṣàkẹ́ rántí ìtan ilé ẹ̀kọ tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin a máa sọ fún-un. "Àwọn Tíṣà a máa mú pankẹ́ré lọ́wọ́". "Àwọn Tíṣà a máa nànyàn".
"Tani yóò jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀ mi?" Àṣàkẹ́ ṣe àsarò.
Ní àfẹ̀mọ́júmọ́, Àkùkọ kọ "kùkùrúùku". Àṣàkẹ́ dìde fùúyà. Ó lọ sí balùwẹ̀. Gẹ́rẹ́ tí ó ṣe tán, Ó wọ aṣọ ilé ìwé rè, ìbọ̀sẹ̀, pẹ̀lú bàtà titun.
Màmá rẹ̀ mu dání lọ́wọ́. Ilé-ẹ̀kọ́ yá.
Nígbà tí wọ́n dé ilé ẹ̀kọ́, Àṣàkẹ́ rò lọ́kàn ara rẹ, "èéṣe tí àwọn wọ̀nyí í ṣe kéré jọjọ?" Ó wùú láti béèrè l'ọ́wọ́ ìyá rẹ̀, sùgbọ́n àya rẹ ń já.
Àwọn méjéèjì dé ẹnu ìloro ilé ẹ̀kọ́. Àṣàkẹ́ gbọ́ ohùn agogo, "gbagaun, gbagaun, gbagaun".
Agogo ilé ẹ̀kọ́ lò n dún.
Àṣàkẹ́ wo wájú. Ó rí àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ bí wọ́n tí ń sáré wọ ìnú ìloro ilé-ẹ̀kọ́.
Ó já ọwọ́ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ ìyá rẹ̀. Òun náà sáré tẹ̀lé wọn.
Nínú 'yàrá íkẹ́kọ̀ọ́, iwájú ni Àṣàkẹ jókòó sí.
Ó ṣe àkíyèsí pé òun ló tóbi jù, òun ló já jù, òun ló dàgbà jù nínú 'yàrá ikẹkọ́ọ.
Tíṣà Àṣàkẹ fẹ́ràn rẹ̀ púpọ̀ nítorí pé ó jẹ́ akínkanjú àti pé ó já fáfá.
Àwọn akẹẹgbẹ́ rẹ̀ máa ń mu ṣiré nítorí pé òun ló tóbi jù, òun ló gajù, òun ló sì dàgbà jù láàrin wọn.
Òun kìí dà wọn lóhùn nítorí pe o pinnu láti di dókítà.

