Adùn, Ọmọ Arẹwà Kan
Taiwo Ẹhinẹni
Wiehan de Jager

Adùn rẹwà púpọ̀. Gbogbo ọkùnrin ní abúlé rẹ̀ ni ó fẹ́ fẹ́ ẹ. Ṣùgbọ́n Adùn kò gbà fún wọn.

1

Ní ọjọ́ ọjà kan, ọkùnrin kan yá ẹsẹ̀ láti ọwọ́ ọkùnrin kan, ó tún yá apá àti ara lọ́wọ́ ẹlòmíràn. Lẹ́hìn náà, ọkùnrin yìí pa gbogbo ẹ̀yà yìí pọ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀. Ó sì lọ sí ọjà.

2

Ọkùnrin yìí fẹ́ Adùn, ó sì pinu láti fẹ́ ẹ. Adùn náà fẹ́ràn ìmúra ọkùnrin yìí, ó sì fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ̀. Ọkùnrin yìí wá láti ìlú jínjìn. Adùn sì pinu láti padà pẹ̀lú rẹ̀.

3

Bí Adùn àti ọkùnrin náà ṣe ń lọ́ sí ìlú rẹ̀, ẹni tó ni ẹsẹ̀ gba ẹsẹ̀ náà padà. Lẹ́hìn náà, ẹni tó ni apá gba apá náà padà. Ẹni tó ni ara náà gba ara náà padà.

4

Orí nìkan ni ó kù, orí náà sì ń rìn lọ. Adùn bẹ̀rẹ̀ sì í bẹ̀rù ṣùgbọ́n kò sá lọ. Wọ́n dé ilé orí náà.

5

Ní ọjọ́ kẹjì, kí orí náà tó lọ sí oko rẹ̀, ó sọ fún Ìjàpá, "Tí Adùn bá fẹ́ sá lọ, fọn fèrè yìí láti tó mi létí."

6

Bí orí náà ṣe fẹ́ máa lọ, Adùn bẹ̀rẹ̀ sí ní í kó ẹrù rẹ̀. Lẹ́hìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í sá lọ.

7

Nígbà tí Ìjàpá ri, ó fọn fèrè, "Orí, orí, Adùn fẹ́ sá lọ̀" Ìjàpá kígbe.

8

Orí náà sá lọ bá Adùn. "Ó ní "Níbo ni o rò pé o ń lọ?" Adùn padà lọ sí ilé orí náà."

9

Lẹ́hìn náà, Adùn lọ bá babaláwo láti mọ nǹkan tí òun lè ṣe. Babaláwo náà sọ fún, "Lọ ra àwọn àkàrà. Fi àwọn kan sínú epo pupa, kí o sì fi sínú ìho Ìjàpá."

10

Adùn tẹ̀lé ìlànà babaláwo náà.

11

Ní ọjọ́ kejì, ó kó àwọn nǹkan rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ. Nígbà tí Ìjàpá mú ìho láti fọn, àwọn àkàrà aládùn náà bẹ̀rẹ̀ sí í jábọ́ sí ẹnu rẹ̀.

12

Ìjàpá jẹ, jẹ, jẹ. Adùn sì sá lọ.

13
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Adùn, Ọmọ Arẹwà Kan
Author - Taiwo Ẹhinẹni
Illustration - Wiehan de Jager
Language - Yoruba
Level - Longer paragraphs