Ramúramù ewúrẹ́
Olajide Akoni
Offei Tettey Eugene

Ramúramù jẹ́ ewúrẹ́ tí ó maá n kígbe gan an.

Yí ó máa pe 'mẹ̀ẹ́ẹ̀', tí àwọn ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ bá n sùn lọ́wọ́.

1

Ní ọjọ́ kan, ó fun ilẹ̀kùn ìbùsun rẹ̀ ní ìpá, ilẹ̀kùn ṣí! Ó subú lulẹ̀, Ó wó kè, Ó ní, "Mo bọ́!"

Ó dá lójú pé aiyé ìyanu n bẹ tí ojú rẹ ẹ̀ máa rí níta!

2

Aláriwo, ajá kékeré oko náà, rí Ramúramù, ó kígbe, "Wúfù! Wúfù! O kò gbọ́dọ̀ lọ!" Ṣùgbọ́n Ramúramù fún un nígbò.

3

Ramúramù sáré gun orí òkè, ó wo òfurufú.

"Èhén èn!" ó kígbe. "Mo ti bọ́ lóòótọ́."

4

Ó fò sókè, ó búsẹ́ẹ́rín, ó yí títí ó fi dé ìsàlẹ̀ òkè náà, ó ba fara gbá nkan, ó dún, "Gbáún!"

Ṣaléwá màálù ló kọ lù!

5

Ó n fi imú túlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ koríko, ṣùgbọ́n ó tú dàànù, ó ba ojú jẹ́.

6

Lẹ́yìn náà, ó rí àwọn adìyẹ tó n jẹ àgbàdo, ó sì lé wọn kiri bí wọ́n n se n kígbe, "Kú, kú, kú," gbogbo iyẹ̀ wọ́n sì n tú ká.

7

Láìpẹ́, ó tún jí iṣu lọ́dọ̀ ẹlẹ́dẹ̀, ó sì sáré gan pẹ̀lú nkan tí ó jí!

8

Ó dé ibi tí ilẹ̀ tí tẹ́jú, pẹ̀lú òmùgọ̀ àgùntàn, ó sì rìn wọlé láti máa jẹun.

9

Ó gbọ́ àjèjì ìfé to jẹ́ kí àgùntàn parapọ̀ láti sá lọ, ṣùgbọ́n kò ya lára; ó dùbúlẹ̀, ó sùn lọ.

10

Ó gbọ́ ẹ̀ẹ̀rín búburú, ó tají, ó gbòórùn líle tó jáa láyà.

11

Ramúramù sá pẹ̀lú gbogbo okun, bí ẹ̀ẹ̀rín búburú náà ṣe n tẹ̀le.

Ó sá títí ó fi dé ìbùsun rẹ̀, láti ìgbà náà, kò dá laba láti sá lọ mó.

12
You are free to download, copy, translate or adapt this story and use the illustrations as long as you attribute in the following way:
Ramúramù ewúrẹ́
Author - Olajide Akoni
Illustration - Offei Tettey Eugene
Language - Yoruba
Level - First paragraphs